Gratitude
Tope Alabi
6:07Oro kan soso Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso Ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso Beeni mo wi Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso Ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso Oro laseda fi d'aye at'orun Ohun gbogbo to wa ninu e, oro lo fi da B'aye at'orun ba yi pada, oro l'Olorun yio wa titi lai Tori oro ledidi ohun gbogbo Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso Ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso Oro lagbara e wa wo'di oro aye Ohun t'aye n pe loro ni gbolohun Ninu oro aye ni won n so ofo Ninu oro won ni, ase Ohun oro aye n se fun aye 'Jamba lo po ninu won Oruko t'aye ba p'oro ni yio je Ibi ni won fi n se fun 'ra won Eda gbogbo ti n gb'aye e ma ba mi bo o Ibudoko ero to n lo si irin ajo Laperosoko ti n p'ariwo E wole, hundred naira lowo ori enikan Onikaluku wole soko Loko ba kun ni won ba si Won m'ori le irin ajo won Igba t'an mi a gb'owo oko tan pata Baba kan lo ko to lohun o ni san'wo pe O san hundred naira, o fe gba forty naira pada Gbogbo ero to mbe ninu oko, won ko ha! wipe baba se bee ti gbo tele Conductor lohun o ni gba laabo, baba lohun o ni won kun Enikan ninu oko lohun a fi kun Baba ba ni ko ni dara f'eni ba fi kun Gbogbo ero to mbe ninu oko ba gb'enu won dake Igba baba de 'bi to n lo Lo ba wo conductor sokale loko, lo ba ni o gbe Ka to wi, ka to fo, ero ti pe le won lori Ijamba laye ma fi n wa (beeni) B'agbara aye ba ti n gun won (e o ni se won) B'ika ba n gun eniyan ibi, won a maa to'ja tase kiri beeni Oro ni won fi n ja, e wa wo'di oro t'aye n pon le Lo ba p'ase lati 'nu oro, t'a wa ninu Olorun ti a ko ri Ko to wi tan, conductor ti bo'so sonu Lo ba mo'ri le 'gbo S'e ti r'aye oro agbara aye, opelope arakunrin kan T'o m be ninu oko to j'omo Olorun, to m'oro iseda To da aye, to d'ohun gbogbo Oro Olorun to nipa oro eyi ti a ti ko wipe, ko s'ohun ija kan ti a se si o ti yio pa o lara Ati pe t'aa leni naa, ti n wi, to si n se, nigba ti Oluwa ko p'ase re o Nitorina, ni oruko Jesu Olugbala, conductor pada wa 'bi, wo'so k'ori e si pe Lara ba ro baba oloro aye, a b'e o r'oro to n gb'oro mi Bi ko ba se ti Jesu, opo eda lo ti d'eja ko s'awon won Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso Ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o Oro kan soso, o le tun se, oro kan soso Eniyan inu aye, e je k'a fura o Satani n s'oro bi agbon Elomiran ki a to bi won o, lowo awon ota ti te won Elomiran nigba t'a bi won tan, laarin egbe, nibi ise, owo ika t'a gbe leni lori ta o mo, lorisirisi ijamba ti n se ni E je ka gb'adura eniyan o K'aye ma f'oro won tun ni da Mo f'owo d'eleda mi mu K'ori mi ma gba 'bode oro o Oro kan soso to s'eda aye e, oro kan ni Oro kan soso to n gbe oro mi, oro kan soso Gbogbo ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o Oro iseda, o so won di're pada, oro o Oro kan soso to s'eda aye e, oro kan ni Oro kan soso to n gbe oro mi, oro kan soso Gbogbo ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o Oro iseda, o so won di're pada, oro o Oro kan soso to s'eda aye e, oro kan ni Oro kan soso to n gbe oro mi, oro kan soso Gbogbo ohun ti a ti f'oro baje ninu aye mi o Oro iseda, o so won di're pada, oro o