Ajosepo

Ajosepo

Beautiful Nubia And The Roots Renaissance Band

Альбом: Olumuyiwa
Длительность: 4:06
Год: 2023
Скачать MP3

Текст песни

Ìṣọ'kan ni ó gbé wa d'ókè yí o
Ìgboyà ni ó gbé wa dé 'bi iyì
Òtítọ' ni ó mú wa d'òmìnira
Ìrẹ'pọ' ni ó gbé wa dé 'bi ayọ

Kí l'ẹ wí? À mí ṣe'un à jọ ṣe pọ'
À mí rìnrìn à jọ rìn pọ
À mí jẹ'un à jọ je pọ
À mí m'oun à jọ mu pọ
Alábòsí bìlà, jẹ' k'á r'ọ'nà

Ìfura, ṣe b'óun loògùn àgbà o
Sẹ mí nbi ẹ', ṣe b'óun ní m'ọ'rẹ' gùn
Òtítọ' ni ó mú wa d'òmìnira
Ìrẹ'pọ' ni ó gbé wa dé 'bi ògo

Kí l'ẹ wí? À mí r'oun à jo rò pọ'
À mí fa'un à jọ fà pọ
À mí ru'un à jọ rù pọ
À mí wo'bi à jọ wọ' pọ
Oníbàjẹ', yàgò, k'á rí 'bi gbà

À mí ṣe'un à jọ ṣe pọ' (à jọ ṣe)
À mí rìnrìn à jọ rìn pọ' (à jọ rìn)
À mí jẹ'un à jọ jẹ pọ' (à jọ jẹ)
À mí m'oun à jọ mu pọ' (à jọ mu)
À mí r'oun à jọ rò pọ' (à jọ rò)
À mí fa'un à jọ fà pọ' (à jọ fà)
À mí ru'un à jọ rù pọ' (à jọ rù)
À mí wo'bi à jọ wọ' pọ' (à jọ wọ')

Alábòsí, bìlà, jẹ' k'á r'ọ'nà

Oníbàjẹ', yàgò, k'á rí 'bi gbà

Aláìmọ́ kàn, bílà, jẹ' k'á r'ọ'nà

Oníyangí, yàgò, epo ńmọ rù

Jẹ' k'á r'ọ'nà

Ka ṣeun to dára, ka ṣeun to sùn wọn (k'á rí 'bi gbà)

Alábòsí, bìlà (jẹ' k'á r'ọ'nà)
Ka ṣeun to dára, ka ṣeun to súnwọn (k'á rí 'bi gbà)

Oníbàjẹ', yàgò (Jẹ' k'á r'ọ'nà)
Ka ṣeun to dára, ka ṣeun to súnwọn (k'á rí 'bi gbà)