Fun Anu To Po B' Yanrin
Bode Afolabi
2:441. Ji, okan mi, dide layo, Korin iyin Olugbala; Ola Re bere orin mi: ‘Seun nife Re ti po to! 2. O ri mo segbe n’ isubu, Sibe, O fe mi l’ afetan; O yo mi ninu osi mi: ‘Seun ‘fe Re tit obi to! 3. Ogun ota dide si mi, Aiye at’ Esu ndena mi, On nmu mi la gbogbo re ja; ‘Seun ‘fe Re ti n’ipa to! 4. ‘Gba ‘yonu de, b’ awosanma, T’o su dudu t’o nsan ara; O duro ti mi larin re: ‘Seun ‘fe Re ti dara to! 5. ‘Gbagbogbo l’okan ese mi Nfe ya lehin Oluwa mi; Sugbo bi mo ti ngbagbe Re, Iseun ife Re ki ye, 6. Mo fere f’aiye sile na, Mo fe bo low’ ara iku; A! k’ emi ‘kehin mi korin Iseun ife Re n’ iku. 7. Nje k info lo, ki nsi goke, S’ aiye imole titi lai; Ki nf’ ayo iyanu korin Iseun ife Re lorun